Decca Records
Decca Records Jẹ́ ilé-iṣẹ́ agbórin-jáde ti orílẹ̀-èdè Britain àti Amẹ́ríkà tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1929 láti ọwọ́ olùdásílẹ̀ rẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Edward Lewis lẹ́yìn tí ó ra ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn ti gramophone tí ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí The Decca Gramophone Company. Ó dá ẹ̀ka ilé-isẹ́ yí kalẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ Decca. Orúkọ yí gbẹ̀rẹ̀gẹ̀-jigẹ̀ ṣáájú kí ogun agbaye ẹlẹkeji tó bẹ̀rẹ̀. Láìpẹ́, ilé-isẹ́ yí tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Amerika yí tún bọ́ si abẹ́ MCA Inc. ní ọdún 1962. Ilé-isẹ́ Decca tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Briatain ni ó ti ní àwọn irinṣẹ́ ìgbàlódé ti Ó si ti lààmì
Decca ti gbìyànjú gidi pẹ̀lú bí wọ́n ṣe gbé onírúurú àwọn ònkọrin,, akọrin ẹlẹ́bùn ọpọlọ oríṣiríṣi jáde ní ilẹ̀ Amẹrika àti Britain láàrín ogún ọdún àkọ́kọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Lára àwọn ti wọ́n ti gbé jáde ní Amẹ́ríkà ni:
- Gertrude Lawrence,
- George Formby,
- Jack Hylton
- Vera Lynn
- Bing Crosby,
- Al Jolson,
- Andrews Sisters
- Mills Brothers.
Lara awọn ti wọn ti gbe jade ni Amẹrika ni:
- Bill Haley & His Comets
- Buddy Holly
- Elvis Presley
- Tommy Steele,
- Lonnie Donegan,
- Chuck Berry
- Johnny Cash
- Eddie Cochran àti
- the Rolling Stones.
Lẹ́yìn ogun àgbáyé ẹlẹ́keji, ilé-isẹ́ Decca ti di àpèwáwò fún gbogbo olórin àti oríṣiríṣi irúfẹ́ orin kò báà wù wọ́n láti má a kọ Láàrín ọdún 1958 sí ọdún 1965, wọ́n ṣe àpèuwe aṣeyọri ile-iṣẹ ọhun gẹgẹ bi me-riyii-ri to ga julọ lawujọ awọn agborinjade.