Jump to content

Derby County F.C.

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àyọkà yìí jẹ mọ́ nípa the men's team. Fún the women's team, ẹ wo: Derby County F.C. Women.
Derby County
Fáìlì:Derby County crest.svg
Full nameDerby County Football Club
Nickname(s)The Rams
Short nameDerby
Founded1884; ọdún 141 sẹ́yìn (1884)
GroundPride Park Stadium
(Capacity: 33,597)
OwnerDavid Clowes
ChairmanDavid Clowes
Head coachJohn Eustace
LeagueÀdàkọ:English football updater
Àdàkọ:English football updaterÀdàkọ:English football updater
Website[dcfc.co.uk Club home page]
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Home colours
Current season


Derby County Football Club ( /ˈdɑrbi/) jẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ni Derby, England. Ẹgbẹ́ náà ń díje nínú EFL Championship, ìpele kejì ti bọ́ọ̀lù-ẹlẹ́sẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjìlá tí wọ́n dá Football League sílẹ̀ ní ọdún 1888, Derby County sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́sàn-án péré tó ti kópa nínú gbogbo àkókò ti ètò lígì bọ́ọ̀lù-ẹlẹ́sẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (àkókò 126 títí di òpin àkókò 2024–25), pẹ̀lú gbogbo wọn àfi mẹ́fà nínú àwọn ìpele méjì óke.

A dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ ní ọdún 1884 látọwọ́ William Morley gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka ti Derbyshire County Cricket Club. Ìgbà gíga rẹ̀ nínú ìdíje wáyé ní àwọn ọdún 1970 nígbà tí ó gba ife ẹ̀yẹ First Division nígbà méjì òtòtò, ó sì kópa nínú àwọn ìdíje Yúróòpù pàtàkì nígbà mẹ́rin, ó dé ìpele àbọ̀-ipari European Cup, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀bùn ife kékeré. Ní àfikún, ẹgbẹ́ náà jẹ́ ẹgbẹ́ tó lágbára ní àwọn àkókò àárín ọdún ogun àgbáyé kéjì – ó gbé ipò kejì nínú lígì nígbà méjì ní àwọn ọdún 1930 – ó sì gba ife ẹ̀yẹ FA Cup àkọ́kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ògùn àgbáyé ní ọdún 1946.

Àwọn àwọ̀ aṣọ ti Ẹgbẹ́ na ń wo ni ilé jẹ́ dúdú àti funfun láti àwọn ọdún 1890. Orúkọ àpẹẹrẹ ẹgbẹ́ náà, The Rams, jẹ́ ọlá fún ìsopọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú First Regiment of Derby Militia, ẹranko àmì rẹ̀ jẹ́ àgbò, àti orin ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ̀,[1] ìyìn fún àṣà ìpínlẹ̀ náà. Wọ́n ní ìtakora àtijọ́ Pẹ̀lú Ikò agbábọ́ọ̀lù Nottingham Forest, pẹ̀lú ẹni tí wọ́n ń ṣe East Midlands derby.

  1. ↑ "The Derby Ram, 1867". Folkplay. 28 June 2004. http://www.folkplay.info/Texts/86sk--lj.htm.